16. Bẹ̃ ni Jonatani bá ile Dafidi da majẹmu wipe, Oluwa yio si bere rẹ̀ lọwọ awọn ọta Dafidi.
17. Jonatani si tun mu ki Dafidi ki o bura nitoriti o sa fẹ ẹ: o si fẹ ẹ bi o ti fẹ ẹmi ara rẹ̀.
18. Nigbana ni Jonatani wi fun Dafidi pe, ọla li oṣu titun: a o si fẹ ọ kù, nitoriti ipò rẹ yio ṣofo.
19. Bi iwọ ba si duro ni ijọ mẹta, nigbana ni iwọ o si yara sọkalẹ, iwọ o si wá si ibiti iwọ gbe ti fi ara rẹ pamọ si nigbati iṣẹ na wà lọwọ, iwọ o si joko ni ibi okuta Eseli.
20. Emi o si ta ọfà mẹta si ìha ibẹ̀ na, gẹgẹ bi ẹnipe mo ta si àmi kan.