28. Ati awọn kan ninu wọn ni itọju ohun elo ìsin, lati ma kó wọn sinu ile ati si ode ni iye.
29. Ninu wọn li a yàn lati ma bojuto ohun elo, ati gbogbo ohun elo ibi mimọ́, ati iyẹfun kikunna, ati ọti-waini, ati ororo, ati ojia, ati turari.
30. Ati omiran ninu awọn ọmọ awọn alufa si fi turari ṣe ororo.
31. Ati Mattitiah, ọkan ninu awọn ọmọ Lefi, ti iṣe akọbi Ṣallumu ọmọ Kora, li o nṣe alabojuto iṣẹ ohun ti a ndín.
32. Ati ninu awọn arakunrin wọn ninu awọn ọmọ Kohati li o nṣe itọju akara-ifihan, lati mã pese rẹ̀ li ọjọjọ isimi.
33. Wọnyi si li awọn akọrin, olori awọn baba awọn ọmọ Lefi, nwọn kò ni iṣẹ ninu iyara wọnni; nitori ti nwọn wà lẹnu iṣẹ wọn lọsan ati loru.
34. Awọn wọnyi ni olori baba awọn ọmọ Lefi, ni iran wọn, olori ni nwọn: awọn wọnyi ni ngbe Jerusalemu.
35. Ati ni Gibeoni ni baba Gibeoni ngbe, Jegieli, orukọ aya ẹniti ijẹ Maaka.
36. Akọbi ọmọ rẹ̀ si ni Abdoni, ati Suri ati Kiṣi, ati Baali, ati Neri, ati Nadabu,
37. Ati Gedori, ati Ahio, ati Sekariah ati Mikloti.
38. Mikloti si bi Ṣimeamu. Awọn wọnyi si mba awọn arakunrin wọn gbe ni Jerusalemu, kọju si awọn arakunrin wọn.
39. Neri si bi Kiṣi, Kiṣi si bi Saulu, Saulu si bi Jonatani, ati Malkiṣua, ati Abinadabu, ati Eṣbaali.
40. Ati ọmọ Jonatani ni Merib-baali; Merib-baali si bi Mika.
41. Ati awọn ọmọ Mika ni Pitoni, ati Meleki, ati Tarea, ati Ahasi.
42. Ahasi si bi Jara; Jara si bi Alemeti, ati Asmafeti, ati Simri, Simri si bi Mosa,
43. Mosa si bi Binea, ati Refaiah ọmọ rẹ̀, Eleasa ọmọ rẹ̀, Aseli ọmọ rẹ̀.
44. Aseli si bi ọmọ mẹfa, orukọ wọn ni wọnyi; Asrikamu, Bokeru, ati Iṣmaeli, ati Ṣeariah, ati Obadiah ati Hanani. Wọnyi li awọn ọmọ Aseli.