18. Titi di isisiyi awọn ti o duro li oju-ọ̀na ọba niha ilà-õrùn; adena ni wọn li ẹgbẹ awọn ọmọ Lefi.
19. Ati Ṣallumu ọmọ Kore, ọmọ Ebiasafu, ọmọ Kora, ati awọn arakunrin rẹ̀, ti ile baba rẹ̀, awọn ọmọ Kora, ni mbẹ lori iṣẹ ìsin na, olutọju iloro agọ na; awọn baba wọn ti mbẹ lori ibudo Oluwa ti nwọn ima ṣọ atiwọ̀le na.
20. Ati Finehasi ọmọ Eleasari ni olori lori wọn ni igba atijọ, Oluwa si wà pẹlu rẹ̀.
21. Sekariah ọmọ Meṣelemiah ni adena ilẹkun agọ ajọ enia.
22. Gbogbo wọnyi ti a ti yàn lati ṣe adena loju iloro, jẹ igba o le mejila. A ka awọn wọnyi nipa idile wọn ni ileto wọn, awọn ẹniti Dafidi ati Samueli, ariran, ti yàn nitori otitọ wọn.
23. Bẹ̃li awọn wọnyi ati awọn ọmọ wọn nṣẹ abojuto iloro ile Oluwa, eyini ni ile agọ na fun iṣọ.
24. Ni igun mẹrẹrin ni awọn adena mbẹ, niha ilà-õrùn, ìwọ-õrún, ariwa ati gusu.
25. Ati awọn arakunrin wọn ngbe ileto wọn, lati ma wá pẹlu wọn ni ijọ ekeje lati igba de igba.
26. Nitoriti awọn ọmọ Lefi wọnyi jẹ awọn olori adena mẹrin, nwọn si wà ninu iṣẹ na, nwọn si wà lori iyara ati ibi iṣura ile Ọlọrun.
27. Nwọn a si ma sùn yi ile Ọlọrun ka, nitori ti nwọn ni itọju na, ati ṣiṣi rẹ̀ li orowurọ jẹ ti wọn.
28. Ati awọn kan ninu wọn ni itọju ohun elo ìsin, lati ma kó wọn sinu ile ati si ode ni iye.
29. Ninu wọn li a yàn lati ma bojuto ohun elo, ati gbogbo ohun elo ibi mimọ́, ati iyẹfun kikunna, ati ọti-waini, ati ororo, ati ojia, ati turari.