15. Ati Bakbakkari, Hereṣi, ati Galali, ati Mattaniah ọmọ Mika, ọmọ Sikri, ọmọ Asafu;
16. Ati Obadiah ọmọ Ṣemaiah, ọmọ Galali, ọmọ Jedutuni, ati Berekiah ọmọ Asa, ọmọ Elkanah, ti ngbe ileto awọn ara Netofa.
17. Awọn adena si ni Ṣallumu, ati Akkubu, ati Talmoni, ati Ahimani, ati awọn arakunrin wọn; Ṣallumu li olori;
18. Titi di isisiyi awọn ti o duro li oju-ọ̀na ọba niha ilà-õrùn; adena ni wọn li ẹgbẹ awọn ọmọ Lefi.
19. Ati Ṣallumu ọmọ Kore, ọmọ Ebiasafu, ọmọ Kora, ati awọn arakunrin rẹ̀, ti ile baba rẹ̀, awọn ọmọ Kora, ni mbẹ lori iṣẹ ìsin na, olutọju iloro agọ na; awọn baba wọn ti mbẹ lori ibudo Oluwa ti nwọn ima ṣọ atiwọ̀le na.
20. Ati Finehasi ọmọ Eleasari ni olori lori wọn ni igba atijọ, Oluwa si wà pẹlu rẹ̀.
21. Sekariah ọmọ Meṣelemiah ni adena ilẹkun agọ ajọ enia.
22. Gbogbo wọnyi ti a ti yàn lati ṣe adena loju iloro, jẹ igba o le mejila. A ka awọn wọnyi nipa idile wọn ni ileto wọn, awọn ẹniti Dafidi ati Samueli, ariran, ti yàn nitori otitọ wọn.
23. Bẹ̃li awọn wọnyi ati awọn ọmọ wọn nṣẹ abojuto iloro ile Oluwa, eyini ni ile agọ na fun iṣọ.