10. Ati ninu awọn alufa; Jedaiah, ati Jehoiaribu ati Jakini,
11. Ati Asariah ọmọ Hilkiah, ọmọ Meṣullamu, ọmọ Sadoku, ọmọ Meraiotu, ọmọ Ahitubu olori ile Ọlọrun;
12. Ati Adaiah ọmọ Jerohamu, ọmọ Paṣuri, ọmọ Malkijah, ati Maasai ọmọ Adieli, ọmọ Jasera, ọmọ Meṣullamu, ọmọ Meṣillemiti, ọmọ Immeri;
13. Ati awọn arakunrin wọn olori ile baba wọn, ẹgbẹsan o din ogoji; awọn alagbara akọni ọkunrin fun iṣẹ ìsin ile Ọlọrun.
14. Ati ninu awọn ọmọ Lefi; Ṣemaiah ọmọ Haṣubu, ọmọ Asrikamu, ọmọ Haṣabiah, ninu awọn ọmọ Merari;
15. Ati Bakbakkari, Hereṣi, ati Galali, ati Mattaniah ọmọ Mika, ọmọ Sikri, ọmọ Asafu;