1. A si ka iye gbogbo Israeli ni idile idile wọn; si kiyesi i, a kọ wọn sinu iwe awọn ọba Israeli: Juda li a si kó lọ si Babiloni nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀.
2. Awọn ti o tetekọ gbe ilẹ ini wọn, ati ilu wọn li awọn ọmọ Israeli, awọn alufa, ati awọn ọmọ Lefi ati awọn Netinimu.
3. Ni Jerusalemu ni, ninu awọn ọmọ Juda, ati ninu awọn ọmọ Benjamini, ati ninu awọn ọmọ Efraimu, ati Manasse ngbe;
4. Utai ọmọ Ammihudi, ọmọ Omri, ọmọ Imri, ọmọ Bani, ninu awọn ọmọ Faresi ọmọ Juda.
5. Ati ninu awọn ara Ṣilo, Asaiah akọbi, ati awọn ọmọ rẹ̀.