38. Aseli si ni ọmọkunrin mẹfa, orukọ wọn ni wọnyi, Asrikamu, Bokeru, ati Iṣmaeli, ati Seraiah, ati Obadiah, ati Hanani. Gbogbo awọn wọnyi li ọmọ Aseli.
39. Awọn ọmọ Eṣeki arakunrin rẹ̀ si ni Ulamu akọbi rẹ̀, Jehuṣi ekeji, ati Elifeleti ẹkẹta.
40. Awọn ọmọ Ulamu si jẹ alagbara akọni ọkunrin, tafatafa, nwọn si li ọmọ pupọ ati ọmọ ọmọ adọjọ. Gbogbo wọnyi li awọn ọmọ Benjamini.