1. Kro 8:25-36 Yorùbá Bibeli (YCE)

25. Ati Ifediah, ati Penueli, ni awọn ọmọ Ṣaṣaki;

26. Ati Samṣerai, ati Sehariah, ati Ataliah,

27. Ati Jaresiah, ati Eliah, ati Sikri, ni awọn ọmọ Jerohamu.

28. Wọnyi li olori awọn baba, nipa iran wọn, awọn olori. Awọn wọnyi ni ngbe Jerusalemu.

29. Ni Gibeoni ni baba Gibeoni si ngbe; orukọ aya ẹniti ijẹ Maaka:

30. Ọmọ rẹ̀ akọbi si ni Abdoni, ati Suri, ati Kiṣi, ati Baali, ati Nadabu,

31. Ati Gedori, ati Ahio, ati Sakeri,

32. Mikloti si bi Ṣimea. Awọn wọnyi pẹlu si mba awọn arakunrin wọn gbe Jerusalemu, nwọn kọju si ara wọn.

33. Neri si bi Kiṣi, ati Kiṣi si bi Saulu, ati Saulu si bi Jonatani, ati Milkiṣua, ati Abinadabu, ati Esbaali.

34. Ọmọ Jonatani si ni Meribaali; Meribaali si bi Mika.

35. Awọn ọmọ Mika ni Pitoni ati Meleki, ati Tarea, ati Ahasi.

36. Ahasi si bi Jehoadda; ati Jehoadda si bi Alemeti, ati Asmafeti, ati Simri: Simri si bi Mosa;

1. Kro 8