1. Kro 7:22-24 Yorùbá Bibeli (YCE)

22. Efraimu baba wọn si ṣọ̀fọ li ọjọ pupọ, awọn arakunrin rẹ̀ si wá lati tù u ninu.

23. Nigbati o si wọle tọ̀ aya rẹ̀ lọ, o loyun o si bi ọmọ kan, on si pè orukọ rẹ̀ ni Beria, nitoriti ibi ba ile rẹ̀.

24. Ọmọ rẹ̀ obinrin ni Sera, ẹniti o tẹ̀ Bet-horoni dó, ti isalẹ ati ti òke, ati Usseni Ṣera.

1. Kro 7