1. Kro 7:11-15 Yorùbá Bibeli (YCE)

11. Gbogbo awọn wọnyi ọmọ Jediaeli, nipa olori awọn baba wọn, akọni alagbara enia, jẹ ẹgbãjọ o le ẹgbẹfa ọmọ-ogun, ti o le jade lọ si ogun.

12. Ati Ṣuppimu, ati Huppimu, awọn ọmọ Iri, ati Huṣimu, awọn ọmọ Aheri.

13. Awọn ọmọ Naftali: Jasieli, ati Guni, ati Jeseri, ati Ṣallumu, awọn ọmọ Bilha.

14. Awọn ọmọ Manasse; Aṣrieli, ti aya rẹ̀ bi: (ṣugbọn obinrin rẹ̀, ara Aramu, bi Makiri baba Gileadi:

15. Makiri si mu arabinrin Huppimu, ati Ṣuppimu li aya, orukọ arabinrin ẹniti ijẹ Maaka,) ati orukọ ekeji ni Selofehadi: Selofehadi si ni awọn ọmọbinrin.

1. Kro 7