1. Kro 6:76-81 Yorùbá Bibeli (YCE)

76. Ati lati inu ẹ̀ya Naftali; Kedeṣi ni Galili pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Hammoni pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Kirjataimu pẹlu ìgberiko rẹ̀.

77. Fun iyokù awọn ọmọ Merari li a fi Rimmoni pẹlu ìgberiko rẹ̀ fun, Tabori pẹlu ìgberiko rẹ̀, lati inu ẹ̀ya Sebuluni:

78. Ati li apa keji Jordani leti Jeriko, ni iha ariwa Jordani, li a fi Beseri li aginju pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Jasa pẹlu ìgberiko rẹ̀ fun wọn, lati inu ẹ̀ya Rubeni,

79. Ati Kedemoti pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Mefaati pẹlu ìgberiko rẹ̀:

80. Ati lati inu ẹ̀ya Gadi, Ramoti ni Gileadi pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Mahanaimu pẹlu ìgberiko rẹ̀.

81. Ati Heṣboni pẹlu ìgberiko rẹ̀, ati Jaseri pẹlu ìgberiko rẹ̀.

1. Kro 6