1. Kro 6:30-32 Yorùbá Bibeli (YCE)

30. Ṣimea ọmọ rẹ̀, Haggiah ọmọ rẹ̀, Asaiah ọmọ rẹ̀,

31. Wọnyi si ni awọn ti Dafidi yàn ṣe olori iṣẹ orin ni ile Oluwa, lẹhin igbati apoti-ẹ̀ri Oluwa ti ni isimi.

32. Nwọn si nfi orin ṣe isin niwaju ibugbe agọ ajọ, titi Solomoni fi kọ́ ile Oluwa ni Jerusalemu tan: nwọn si duro ti iṣẹ óye wọn gẹgẹ bi ipa wọn.

1. Kro 6