20. A si ràn wọn lọwọ si wọn, a si fi awọn ọmọ Hagari le wọn lọwọ, ati gbogbo awọn ti o wà pẹlu wọn: nitoriti nwọn kepè Ọlọrun li ogun na, on si gbọ́ ẹ̀bẹ wọn: nitoriti nwọn gbẹkẹ wọn le e.
21. Nwọn si kó ẹran ọ̀sin wọn lọ; ibakasiẹ ẹgbãmẹ̃dọgbọ̀n ati àgutan ọkẹ mejila o le ẹgbãrun, ati kẹtẹkẹtẹ ẹgbã, ati enia ọkẹ marun.
22. Nitori ọ̀pọlọpọ li o ṣubu ti a pa, nitori lati ọdọ Ọlọrun li ogun na. Nwọn si joko ni ipò wọn titi di igbà ikolọ si ìgbekun.
23. Awọn ọmọkunrin àbọ ẹ̀ya Manasse joko ni ilẹ na: nwọn bi si i lati Baṣani titi de Baal-hermoni, ati Seniri, ati titi de òke Hermoni.