1. Kro 5:10-16 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. Ati li ọjọ Saulu, nwọn ba awọn ọmọ Hagari jagun, ẹniti o ṣubu nipa ọwọ wọn: nwọn si ngbe inu agọ wọn ni gbogbo ilẹ ariwa Gileadi.

11. Ati awọn ọmọ Gadi ngbe ọkánkan wọn, ni ilẹ Baṣani titi de Salka:

12. Joeli olori, ati Ṣafamu àtẹle, ati Jaanai, ati Ṣafati ni Baṣani.

13. Ati awọn arakunrin wọn ti ile awọn baba wọn ni Mikaeli, ati Meṣullamu, ati Ṣeba, ati Jorai, ati Jakani, ati Sia, ati Heberi, meje.

14. Wọnyi li awọn ọmọ Abihaili, ọmọ Huri, ọmọ Jaroa, ọmọ Gileadi, ọmọ Mikaeli, ọmọ Jeṣiṣai, ọmọ Jado, ọmọ Busi;

15. Adi, ọmọ Abdieli, ọmọ Guni, olori ile awọn baba wọn.

16. Nwọn si ngbe Gileadi ni Baṣani, ati ninu awọn ilu rẹ̀, ati ninu gbogbo igberiko Ṣaroni, li àgbegbe wọn.

1. Kro 5