36. Ati Elioenai, ati Jaakoba, ati Jeṣohaiah, ati Asaiah, ati Adieli, ati Jesimieli, ati Benaiah,
37. Ati Sisa ọmọ Ṣifi, ọmọ Alloni, ọmọ Jedaiah, ọmọ Ṣimri ọmọ Ṣemaiah;
38. Awọn ti a darukọ wọnyi, ìjoye ni wọn ni idile wọn: ile baba wọn si tan kalẹ gidigidi.
39. Nwọn si wọ̀ oju-ọ̀na Gedori lọ, titi de apa ariwa afonifoji na, lati wá koriko fun agbo ẹran wọn.
40. Nwọn si ri koriko tutù ti o si dara; ilẹ na si gbàye, o si gbe jẹ, o si wà li alafia: nitori awọn ọmọ Hamu li o ti ngbe ibẹ li atijọ.
41. Ati awọn wọnyi ti a kọ orukọ wọn, dé li ọjọ Hesekiah ọba Juda, nwọn si kọlu agọ wọn, ati pẹlu awọn ara Mehuni ti a ri nibẹ, nwọn si bà wọn jẹ patapata titi di oni yi, nwọn si ngbe ipò wọn: nitori koriko mbẹ nibẹ fun agbo ẹran wọn.