11. Kelubu arakunrin Ṣua si bi Mehiri, ti iṣe baba Eṣtoni.
12. Eṣtoni si bi Bet-rafa, ati Pasea, ati Tehinna baba ilu Nahaṣi. Wọnyi li awọn ọkunrin Reka,
13. Ati awọn ọmọ Kenasi; Otnieli, ati Seraiah: ati awọn ọmọ Otnieli; Hatati.
14. Meonotai si bi Ofra: Seraiah si bi Joabu, baba Geharasimu; nitori oniṣọnà ni nwọn.
15. Ati awọn ọmọ Kalebu ọmọ Jefunne; Iru, Ela, ati Naamu: ati awọn ọmọ Ela, ani Kenasi.
16. Ati awọn ọmọ Jehaleleeli; Sifu, ati Sifa, Tiria, ati Asareeli.