5. Wura fun ohun èlo wura, ati fadakà fun ohun èlo fadakà, ati fun oniruru iṣẹ nipa ọwọ awọn ọlọnà. Tani si nfẹ loni lati yà ara rẹ̀ si mimọ fun Oluwa?
6. Nigbana ni awọn olori awọn baba ati awọn ijoye ẹ̀ya Israeli, ati awọn balogun ẹgbẹgbẹrun ati ọrọrun, pẹlu awọn ijoye iṣẹ ọba fi tinutinu ṣe iranlọwọ,
7. Nwọn si fi fun iṣẹ ile Ọlọrun, ti wura ẹgbẹ̃dọgbọ̀n talenti ati ẹgbãrun dramu, ati ti fadakà ẹgbãrun talenti, ati ti bàba ẹgbãsan talenti, ati ọkẹ marun talenti irin.
8. Ati awọn ti a ri okuta iyebiye lọdọ wọn fi i sinu iṣura ile Oluwa, nipa ọwọ Jehieli ara Gerṣoni.
9. Awọn enia si yọ̀, nitori nwọn fi tinutinu ṣe iranlọwọ nitori pẹlu ọkàn pipe ni nwọn fi tinutinu ṣe iranlọwọ fun Oluwa: pẹlupẹlu Dafidi ọba si yọ̀ gidigidi.
10. Nitorina Dafidi fi iyìn fun Oluwa li oju gbogbo ijọ: Dafidi si wipe, Olubukún ni Iwọ Oluwa Ọlọrun Israeli baba wa lai ati lailai!
11. Tirẹ Oluwa ni titobi, ati agbara, ati ogo, ati iṣẹgun, ati ọlá-nla: nitori ohun gbogbo li ọrun ati li aiye tirẹ ni; ijọba ni tirẹ, Oluwa, a si gbé ọ leke li ori fun ohun gbogbo.
12. Ọrọ̀ pẹlu ati ọlá ọdọ rẹ ni ti iwá, iwọ si jọba lori ohun gbogbo; li ọwọ rẹ ni agbara ati ipá wà; ati li ọwọ rẹ ni sisọ ni di nla wà, ati fifi agbara fun ohun gbogbo.