2. Ati pẹlu gbogbo ipa mi ni mo ti fi pèse silẹ fun ile Ọlọrun mi, wura fun ohun ti wura, ati fadakà fun ti fadakà, ati idẹ fun ti idẹ, irin fun ti irin, ati igi fun ti igi; okuta oniki ti a o tẹ̀ bọ okuta lati fi ṣe ọṣọ, ati okuta oniruru àwọ, ati oniruru okuta iyebiye, ati okuta marbili li ọ̀pọlọpọ.
3. Pẹlupẹlu, nitori ni didùn inu mi si ile Ọlọrun mi, mo fi ohun ini mi, eyinì ni wura ati fadakà, fun ile Ọlọrun mi, jù gbogbo eyi ti mo ti pèse silẹ fun ile mimọ́ na,
4. Ẹgbẹ̃dogun talenti wura, ti wura Ofiri, ati ẹ̃dẹgbarin talenti fadakà didara, lati fi bo ogiri ile na:
5. Wura fun ohun èlo wura, ati fadakà fun ohun èlo fadakà, ati fun oniruru iṣẹ nipa ọwọ awọn ọlọnà. Tani si nfẹ loni lati yà ara rẹ̀ si mimọ fun Oluwa?
6. Nigbana ni awọn olori awọn baba ati awọn ijoye ẹ̀ya Israeli, ati awọn balogun ẹgbẹgbẹrun ati ọrọrun, pẹlu awọn ijoye iṣẹ ọba fi tinutinu ṣe iranlọwọ,
7. Nwọn si fi fun iṣẹ ile Ọlọrun, ti wura ẹgbẹ̃dọgbọ̀n talenti ati ẹgbãrun dramu, ati ti fadakà ẹgbãrun talenti, ati ti bàba ẹgbãsan talenti, ati ọkẹ marun talenti irin.
8. Ati awọn ti a ri okuta iyebiye lọdọ wọn fi i sinu iṣura ile Oluwa, nipa ọwọ Jehieli ara Gerṣoni.
9. Awọn enia si yọ̀, nitori nwọn fi tinutinu ṣe iranlọwọ nitori pẹlu ọkàn pipe ni nwọn fi tinutinu ṣe iranlọwọ fun Oluwa: pẹlupẹlu Dafidi ọba si yọ̀ gidigidi.
10. Nitorina Dafidi fi iyìn fun Oluwa li oju gbogbo ijọ: Dafidi si wipe, Olubukún ni Iwọ Oluwa Ọlọrun Israeli baba wa lai ati lailai!