1. Kro 27:5-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

5. Olori ogun kẹta fun oṣù kẹta ni Benaiah ọmọ Jehoiada alufa, olori kan: ẹgbã mejila li o si wà ninu ẹgbẹ tirẹ̀.

6. Eyini ni Benaiah na, akọni enia, ninu awọn ọgbọ̀n, o si jẹ olori awọn ọgbọ̀n: Amisabadi ọmọ rẹ̀ si wà ninu ẹgbẹ tirẹ̀.

7. Olori ogun kẹrin fun oṣù kẹrin ni Asaheli arakunrin Joabu, ati Sebadiah ọmọ rẹ̀ lẹhin rẹ̀: ẹgbã mejila li o si wà ninu ẹgbẹ tirẹ̀.

8. Olori ogun karun fun oṣù karun ni Ṣamhuti ara Israhi: ẹgbã mejila li o si wà ninu ẹgbẹ tirẹ̀.

9. Olori ogun kẹfa fun oṣù kẹfa ni Ira ọmọ Ikkeṣi ara Tekoi: ẹgbã mejila li o si wà ninu ẹgbẹ tirẹ̀.

10. Olori ogun keje fun oṣù keje ni Heleṣi ara Peloni, ninu awọn ọmọ Efraimu: ẹgbã mejila li o si wà ninu ẹgbẹ tirẹ̀.

11. Olori ogun kẹjọ fun oṣù kẹjọ ni Sibbekai ara Huṣati ti awọn ara Sarehi: ẹgbã mejila li o si wà ninu ẹgbẹ tirẹ̀.

12. Olori ogun kẹsan fun oṣù kẹsan ni Abieseri ara Anatoti ti awọn ara Benjamini: ẹgbã mejila li o si wà ninu ẹgbẹ tirẹ̀.

1. Kro 27