23. Ṣugbọn Dafidi kò ka iye awọn ti o wà lati ogun ọdun ati awọn ti kò to bẹ̃; nitori ti Oluwa ti wipe on o mu Israeli pọ̀ si i bi irawọ oju ọrun.
24. Joabu ọmọ Seruiah bẹ̀rẹ si ikà wọn, ṣugbọn kò kà wọn tan, nitori ibinu ṣubu lu Israeli nitori na; bẹ̃ni a kò fi iye na sinu iwe Kronika ti Dafidi ọba.
25. Lori awọn iṣura ọba ni Asmafeti ọmọ Adieli wà: ati lori iṣura oko, ni ilu, ati ni ileto, ati ninu odi ni Jonatani ọmọ Ussiah wà:
26. Ati lori awọn ti nro oko, lati ma ro ilẹ ni Esri ọmọ Kelubi wà:
27. Ati lori awọn ọgba-àjara ni Ṣimei ara Ramoti wà: lori eso ọgba-àjara fun iṣura ati ọti-waini ni Sabdi ọmọ Ṣifmi wà: