17. Lori awọn ọmọ Lefi, Haṣabiah ọmọ Kemueli: lori awọn ọmọ Aaroni, Sadoku:
18. Lori Juda, Elihu, ọkan ninu awọn arakunrin Dafidi: lori Issakari, Omri ọmọ Mikaeli:
19. Lori Sebuloni, Iṣmaiah ọmọ Obadiah: lori Naftali, Jerimoti ọmọ Asrieli:
20. Lori awọn ọmọ Efraimu, Hoṣea ọmọ Asasiah: lori àbọ ẹ̀ya Manasse, Joeli ọmọ Pedaiah.
21. Lori àbọ ẹ̀ya Manasse ni Gileadi, Iddo ọmọ Sekariah: lori Benjamini, Jaasieli ọmọ Abneri.
22. Lori Dani, Asareeli ọmọ Jerohamu Awọn wọnyi li olori awọn ẹ̀ya Israeli.
23. Ṣugbọn Dafidi kò ka iye awọn ti o wà lati ogun ọdun ati awọn ti kò to bẹ̃; nitori ti Oluwa ti wipe on o mu Israeli pọ̀ si i bi irawọ oju ọrun.
24. Joabu ọmọ Seruiah bẹ̀rẹ si ikà wọn, ṣugbọn kò kà wọn tan, nitori ibinu ṣubu lu Israeli nitori na; bẹ̃ni a kò fi iye na sinu iwe Kronika ti Dafidi ọba.
25. Lori awọn iṣura ọba ni Asmafeti ọmọ Adieli wà: ati lori iṣura oko, ni ilu, ati ni ileto, ati ninu odi ni Jonatani ọmọ Ussiah wà:
26. Ati lori awọn ti nro oko, lati ma ro ilẹ ni Esri ọmọ Kelubi wà:
27. Ati lori awọn ọgba-àjara ni Ṣimei ara Ramoti wà: lori eso ọgba-àjara fun iṣura ati ọti-waini ni Sabdi ọmọ Ṣifmi wà:
28. Ati lori igi-olifi, ati igi-sikamore ti mbẹ ni pẹ̀tẹlẹ ni Baal-hanani ara Gederi wà; ati lori iṣura ororo ni Joaṣi wà.
29. Ati lori awọn agbo malu ti njẹ̀ ni Ṣaroni ni Ṣitrai ara Ṣaroni wà: ati lori agbo malu ti o wà li afonifoji ni Ṣafati ọmọ Adlai wà: