12. Olori ogun kẹsan fun oṣù kẹsan ni Abieseri ara Anatoti ti awọn ara Benjamini: ẹgbã mejila li o si wà ninu ẹgbẹ tirẹ̀.
13. Olori ogun kẹwa fun oṣù kẹwa ni Maharai ara Netofa, ti awọn ara Sarehi: ẹgbã mejila li o si wà ninu ẹgbẹ tirẹ̀.
14. Olori ogun kọkanla fun oṣù kọkanla ni Benaiah ara Peratoni, ti awọn ọmọ Efraimu: ẹgbã mejila li o si wà ninu ẹgbẹ tirẹ̀.
15. Olori ogun kejila fun oṣù kejila ni Heldai ara Netofa, ti Otnieli: ẹgbã mejila li o si wà ninu ẹgbẹ tirẹ̀.
16. Ati lori awọn ẹ̀ya Israeli: ijoye lori awọn ọmọ Reubeni ni Elieseri ọmọ Sikri: lori awọn ọmọ Simeoni, Ṣefatiah ọmọ Maaka:
17. Lori awọn ọmọ Lefi, Haṣabiah ọmọ Kemueli: lori awọn ọmọ Aaroni, Sadoku:
18. Lori Juda, Elihu, ọkan ninu awọn arakunrin Dafidi: lori Issakari, Omri ọmọ Mikaeli:
19. Lori Sebuloni, Iṣmaiah ọmọ Obadiah: lori Naftali, Jerimoti ọmọ Asrieli:
20. Lori awọn ọmọ Efraimu, Hoṣea ọmọ Asasiah: lori àbọ ẹ̀ya Manasse, Joeli ọmọ Pedaiah.
21. Lori àbọ ẹ̀ya Manasse ni Gileadi, Iddo ọmọ Sekariah: lori Benjamini, Jaasieli ọmọ Abneri.
22. Lori Dani, Asareeli ọmọ Jerohamu Awọn wọnyi li olori awọn ẹ̀ya Israeli.
23. Ṣugbọn Dafidi kò ka iye awọn ti o wà lati ogun ọdun ati awọn ti kò to bẹ̃; nitori ti Oluwa ti wipe on o mu Israeli pọ̀ si i bi irawọ oju ọrun.
24. Joabu ọmọ Seruiah bẹ̀rẹ si ikà wọn, ṣugbọn kò kà wọn tan, nitori ibinu ṣubu lu Israeli nitori na; bẹ̃ni a kò fi iye na sinu iwe Kronika ti Dafidi ọba.
25. Lori awọn iṣura ọba ni Asmafeti ọmọ Adieli wà: ati lori iṣura oko, ni ilu, ati ni ileto, ati ninu odi ni Jonatani ọmọ Ussiah wà:
26. Ati lori awọn ti nro oko, lati ma ro ilẹ ni Esri ọmọ Kelubi wà: