1. Kro 27:1-3 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NJẸ awọn ọmọ Israeli nipa iye wọn, eyini ni, awọn olori baba, ati awọn balogun ẹgbẹgbẹrun, ati ọrọrun, ati awọn ijoye wọn ti nsìn ọba ni olukuluku ọ̀na li ẹgbẹgbẹ, ti nwọle ti si njade li oṣoṣù ni gbogbo oṣù ọdun, jẹ́ ẹgbã mejila.

2. Lori ẹgbẹ kini ti oṣù kini ni Jaṣobeamu ọmọ Sabdieli: ẹgbã mejila li o si wà ninu ẹgbẹ tirẹ̀.

3. Ninu awọn ọmọ Peresi on ni olori fun gbogbo awọn olori ogun ti oṣù ekini.

1. Kro 27