19. Wọnyi ni ipin awọn adena lati inu awọn ọmọ Kore, ati lati inu awọn ọmọ Merari.
20. Lati inu awọn ọmọ Lefi, Ahijah li o wà lori iṣura ile Ọlọrun, ati lori iṣura nkan wọnni ti a yà si mimọ́.
21. Awọn ọmọ Laadani; awọn ọmọ Laadani ara Gerṣoni, awọn olori baba, ani ti Laadani ara Gerṣoni ni Jehieli.
22. Awọn ọmọ Jehieli; Setamu, ati Joeli arakunrin rẹ̀, ti o wà lori iṣura ile Oluwa.
23. Ninu ọmọ Amramu, ati ọmọ Ishari, ara Hebroni, ati ọmọ Ussieli:
24. Ati Ṣebueli ọmọ Gerṣomu, ọmọ Mose, ni onitọju iṣura.
25. Ati awọn arakunrin rẹ̀ nipa Elieseri, Rehabiah ọmọ rẹ̀, ati Jesaiah ọmọ rẹ̀, ati Joramu, ọmọ rẹ̀, ati Sikri ọmọ rẹ̀, ati Ṣelomiti ọmọ rẹ̀.
26. Ṣelomiti yi ati awọn arakunrin rẹ̀ li o wà lori iṣura ohun iyà-si-mimọ́, ti Dafidi ọba ati awọn olori baba, awọn ijoye lori ẹgbẹgbẹrun, ati ọrọrun, ati awọn olori ogun ti yà-si-mimọ́.
27. Lati inu ikogun ti a kó li ogun, ni nwọn yà si mimọ́ lati ma fi ṣe itọju ile Oluwa.
28. Ati gbogbo eyiti Samueli, ariran, ati Saulu, ọmọ Kiṣi, ati Abneri ọmọ Neri, ati Joabu ọmọ Seruiah, yà si mimọ́; gbogbo ohun ti a ba ti yà si mimọ́, ohun na mbẹ li ọwọ Ṣelomiti, ati awọn arakunrin rẹ̀.
29. Ninu awọn ọmọ Ishari, Kenaniah ati awọn ọmọ rẹ̀ li o jẹ ijoye ati onidajọ fun iṣẹ ilu lori Israeli.