13. Nwọn si ṣẹ keké, bi ti ẹni-kekere bẹ̃ni ti ẹni-nla, gẹgẹ bi ile baba wọn, fun olukuluku ẹnu-ọ̀na.
14. Iṣẹ keké iha ila-õrun bọ̀ sọdọ Ṣelemiah. Nigbana ni nwọn ṣẹ keké fun Sekariah ọmọ rẹ̀, ọlọgbọ́n igbimọ; iṣẹ keké rẹ̀ si bọ si iha ariwa.
15. Sọdọ Obed-Edomu niha gusù; ati sọdọ awọn ọmọ rẹ̀ niha ile Asuppimu (yara iṣura).
16. Ti Suppimu ati Hosa niha iwọ-õrun li ẹnu-ọ̀na Ṣalleketi, nibi ọ̀na igòke lọ, iṣọ kọju si iṣọ.
17. Niha ìla-õrùn awọn ọmọ Lefi mẹfa (nṣọ), niha ariwa mẹrin li ojojumọ, niha gusù mẹrin li ojojumọ, ati ninu Asuppimu (ile iṣura) mejimeji.
18. Ni ibasa niha iwọ-õrùn, mẹrin li ọ̀na igòke-lọ ati meji ni ibasa.
19. Wọnyi ni ipin awọn adena lati inu awọn ọmọ Kore, ati lati inu awọn ọmọ Merari.
20. Lati inu awọn ọmọ Lefi, Ahijah li o wà lori iṣura ile Ọlọrun, ati lori iṣura nkan wọnni ti a yà si mimọ́.
21. Awọn ọmọ Laadani; awọn ọmọ Laadani ara Gerṣoni, awọn olori baba, ani ti Laadani ara Gerṣoni ni Jehieli.
22. Awọn ọmọ Jehieli; Setamu, ati Joeli arakunrin rẹ̀, ti o wà lori iṣura ile Oluwa.
23. Ninu ọmọ Amramu, ati ọmọ Ishari, ara Hebroni, ati ọmọ Ussieli: