8. Nwọn si ṣẹ keké fun iṣẹ; gbogbo wọn bakanna bi ti ẹni-kekere bẹ̃ni ti ẹni-nla, ti olukọ bi ti ẹniti a nkọ́.
9. Iṣẹkeké ekini si jade wá fun Asafu si Josefu: ekeji si Gedaliah, ẹniti on pẹlu awọn arakunrin rẹ̀ ati awọn ọmọ rẹ̀, jẹ mejila:
10. Ẹkẹta si Sakkuri, awọn ọmọ rẹ̀ ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila:
11. Ẹkẹrin si Isri, awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila:
12. Ẹkarun si Netaniah, awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila:
13. Ẹkẹfa si Bukkiah, awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila:
14. Ekeje si Jeṣarela, awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila:
15. Ẹkẹjọ si Jeṣaiah, awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila:
16. Ẹkẹsan si Mattaniah, awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila:
17. Ẹkẹwa si Ṣimei, awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila:
18. Ẹkọkanla si Asareeli, awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila:
19. Ekejila si Haṣabiah, awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila:
20. Ẹkẹtala si Ṣubaeli, awọn ọmọ rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, jẹ mejila: