1. PẸLUPẸLU Dafidi ati awọn olori ogun yà ninu awọn ọmọkunrin Asafu, ati Hemani, ati Jedutuni, fun ìsin yi, awọn ẹniti o ma fi duru ati psalteri, ati kimbali kọrin: ati iye awọn oniṣẹ gẹgẹ bi ìsin wọn jẹ:
2. Ninu awọn ọmọ Asafu, Sakkuri, ati Josefu, ati Netaniah, ati Asarela, awọn ọmọ Asafu labẹ ọwọ Asafu, ti o kọrin gẹgẹ bi aṣẹ ọba.
3. Ti Jedutuni: awọn ọmọ Jedutuni; Gedaliah, ati Seri, ati Jeṣaiah, Haṣabiah, ati Mattitiah, ati Ṣimei, mẹfa, labẹ ọwọ baba wọn Jedutuni, ẹniti o fi duru kọrin, lati ma dupẹ fun ati lati ma yìn Oluwa.
4. Ti Hemani: awọn ọmọ Hemani; Bukkiah, Mattaniah, Ussieli, Ṣebueli, ati Jerimotu, Hananiah, Hanani, Eliata, Giddalti, ati Romamtieseri, Joṣbekaṣa, Malloti, Hotiri, Mahasiotu:
5. Gbogbo awọn wọnyi li awọn ọmọ Hemani, woli ọba ninu ọ̀rọ Ọlọrun, lati ma gbé iwo na soke. Ọlọrun si fun Hemani li ọmọkunrin mẹrinla ati ọmọbinrin mẹta.
6. Gbogbo awọn wọnyi li o wà labẹ ọwọ baba wọn, fun orin ile Oluwa, pẹlu kimbali, psalteri ati duru, fun ìsin ile Ọlọrun: labẹ ọwọ ọba, ni Asafu, Jedutuni, ati Hemani wà.
7. Bẹ̃ni iye wọn, pẹlu awọn arakunrin wọn ti a kọ́ li orin Oluwa, ani gbogbo awọn ti o moye, jasi ọrinlugba o le mẹjọ.
8. Nwọn si ṣẹ keké fun iṣẹ; gbogbo wọn bakanna bi ti ẹni-kekere bẹ̃ni ti ẹni-nla, ti olukọ bi ti ẹniti a nkọ́.
9. Iṣẹkeké ekini si jade wá fun Asafu si Josefu: ekeji si Gedaliah, ẹniti on pẹlu awọn arakunrin rẹ̀ ati awọn ọmọ rẹ̀, jẹ mejila: