1. PẸLUPẸLU Dafidi ati awọn olori ogun yà ninu awọn ọmọkunrin Asafu, ati Hemani, ati Jedutuni, fun ìsin yi, awọn ẹniti o ma fi duru ati psalteri, ati kimbali kọrin: ati iye awọn oniṣẹ gẹgẹ bi ìsin wọn jẹ:
2. Ninu awọn ọmọ Asafu, Sakkuri, ati Josefu, ati Netaniah, ati Asarela, awọn ọmọ Asafu labẹ ọwọ Asafu, ti o kọrin gẹgẹ bi aṣẹ ọba.
3. Ti Jedutuni: awọn ọmọ Jedutuni; Gedaliah, ati Seri, ati Jeṣaiah, Haṣabiah, ati Mattitiah, ati Ṣimei, mẹfa, labẹ ọwọ baba wọn Jedutuni, ẹniti o fi duru kọrin, lati ma dupẹ fun ati lati ma yìn Oluwa.
4. Ti Hemani: awọn ọmọ Hemani; Bukkiah, Mattaniah, Ussieli, Ṣebueli, ati Jerimotu, Hananiah, Hanani, Eliata, Giddalti, ati Romamtieseri, Joṣbekaṣa, Malloti, Hotiri, Mahasiotu:
5. Gbogbo awọn wọnyi li awọn ọmọ Hemani, woli ọba ninu ọ̀rọ Ọlọrun, lati ma gbé iwo na soke. Ọlọrun si fun Hemani li ọmọkunrin mẹrinla ati ọmọbinrin mẹta.