5. Bayi li a fi iṣẹkeké pin wọn, iru kan mọ ikeji pẹlu; nitori awọn olori ibi mimọ́, ati olori ti Ọlọrun wà ninu awọn ọmọ Eleasari, ati ninu awọn ọmọ Itamari.
6. Ati Ṣemaiah ọmọ Nataneeli akọwe, ọkan ninu awọn ọmọ Lefi kọ wọn niwaju ọba, ati awọn olori, ati Sadoku alufa, ati Ahimeleki, ọmọ Abiatari, ati niwaju olori awọn baba awọn alufa, ati awọn ọmọ Lefi: a mu ile baba kan fun Eleasari, a si mu ọkan fun Itamari.
7. Njẹ iṣẹkeké ekini jade fun Jehoiaribu, ekeji fun Jedaiah,
8. Ẹkẹta fun Harimu, ẹkẹrin fun Seorimu,
9. Ẹkarun fun Malkijah, ẹkẹfa fun Mijamini,
10. Ekeje fun Hakkosi, ẹkẹjọ fun Abijah,
11. Ẹkẹsan fun Jeṣua, ẹkẹwa fun Ṣekaniah,
12. Ẹkọkanla fun Eliaṣibu, ekejila fun Jakimu,
13. Ẹkẹtala fun Huppa, ẹkẹrinla fun Jeṣebeabu,
14. Ẹkẹdogun fun Bilga, ẹkẹrindilogun fun Immeri,
15. Ẹkẹtadilogun fun Heṣiri, ekejidilogun fun Afisesi,
16. Ẹkọkandilogun fun Petahiah, ogun fun Jehesekeli,
17. Ẹkọkanlelogun fun Jakini, ekejilelogun fun Gamuli,
18. Ẹkẹtalelogun fun Delaiah, ẹkẹrinlelogun fun Maasiah.
19. Wọnyi ni itò wọn ni ìsin wọn lati lọ sinu ile Oluwa, gẹgẹ bi iṣe wọn nipa ọwọ Aaroni baba wọn, bi Oluwa Ọlọrun Israeli ti paṣẹ fun u.
20. Iyokù awọn ọmọ Lefi ni wọnyi: Ninu awọn ọmọ Amramu; Ṣubaeli: ninu awọn ọmọ Ṣubaeli; Jehediah.
21. Nipa ti Rehabiah; ninu awọn ọmọ Rehabiah, ekini Iṣṣiah.