1. Kro 24:26-31 Yorùbá Bibeli (YCE)

26. Awọn ọmọ Merari ni Mali ati Muṣi: awọn ọmọ Jaasiah; Beno;

27. Awọn ọmọ Merari nipa Jaasiah; Beno ati Ṣohamu, ati Sakkuri, ati Ibri.

28. Lati ọdọ Mali ni Eleasari ti wá, ẹniti kò li ọmọkunrin.

29. Nipa ti Kiṣi: ọmọ Kiṣi ni Jerameeli.

30. Awọn ọmọ Muṣi pẹlu; Mali, ati Ederi, ati Jerimoti. Wọnyi li ọmọ awọn ọmọ Lefi nipa ile baba wọn.

31. Awọn wọnyi pẹlu ṣẹ keké gẹgẹ bi awọn arakunrin wọn awọn ọmọ Aaroni niwaju Dafidi ọba ati Sadoku, ati Ahimeleki, ati awọn olori awọn baba awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi: olori awọn baba gẹgẹ bi aburo rẹ̀.

1. Kro 24