23. Awọn ọmọ Hebroni: Jeriah ikini; Amariah ekeji, Jahasieli ẹkẹta, Jekamamu ẹkẹrin.
24. Awọn ọmọ Ussieli; Mika: awọn ọmọ Mika; Ṣamiri.
25. Arakunrin Mika ni Iṣṣiah; ninu awọn ọmọ Iṣṣiah; Sekariah.
26. Awọn ọmọ Merari ni Mali ati Muṣi: awọn ọmọ Jaasiah; Beno;
27. Awọn ọmọ Merari nipa Jaasiah; Beno ati Ṣohamu, ati Sakkuri, ati Ibri.
28. Lati ọdọ Mali ni Eleasari ti wá, ẹniti kò li ọmọkunrin.
29. Nipa ti Kiṣi: ọmọ Kiṣi ni Jerameeli.
30. Awọn ọmọ Muṣi pẹlu; Mali, ati Ederi, ati Jerimoti. Wọnyi li ọmọ awọn ọmọ Lefi nipa ile baba wọn.