7. Ninu awọn ọmọ Gerṣoni ni Laadani, ati Ṣimei.
8. Awọn ọmọ Laadani: Jehieli ni olori, ati Setamu, ati Joeli, mẹta.
9. Awọn ọmọ Ṣimei; Ṣelomiti, ati Hasieli, ati Harani, mẹta. Awọn wọnyi li olori awọn baba Laadani.
10. Awọn ọmọ Ṣimei ni Jahati, Sina, ati Jeuṣi, ati Beriah. Awọn mẹrin wọnyi li ọmọ Ṣimei.
11. Jahati si li olori, ati Sisa ibikeji: ṣugbọn Jeuṣi ati Beriah kò li ọmọ pipọ; nitorina ni nwọn ṣe wà ni iṣiro kan, gẹgẹ bi ile baba wọn.
12. Awọn ọmọ Kohati; Amramu, Ishari, Hebroni ati Ussieli, mẹrin.
13. Awọn ọmọ Amramu; Aaroni ati Mose: a si ya Aaroni si ọ̀tọ, ki o le ma sọ awọn ohun mimọ́ jùlọ di mimọ́, on ati awọn ọmọ rẹ̀ lailai, lati ma jo turari niwaju Oluwa, lati ma ṣe iranṣẹ fun u, ati lati ma sure li orukọ rẹ̀ lailai.
14. Ṣugbọn niti Mose enia Ọlọrun, a kà awọn ọmọ rẹ̀ pọ̀ mọ ẹ̀ya Lefi.
15. Awọn ọmọ Mose ni, Gerṣomu ati Elieseri.
16. Ninu awọn ọmọ Gerṣomu, Sebueli li olori.
17. Awọn ọmọ Elieseri ni Rehabiah olori. Elieseri kò si li ọmọ miran; ṣugbọn awọn ọmọ Rehabiah pọ̀ gidigidi.
18. Ninu awọn ọmọ Ishari; Ṣelomiti li olori.