1. Kro 23:24-32 Yorùbá Bibeli (YCE)

24. Wọnyi ni awọn ọmọ Lefi, bi ile baba wọn; ani olori awọn baba, bi a ti ka wọn ni iye orukọ, nipa ori wọn, awọn ti o ṣiṣẹ ìsin ile Oluwa, lati iwọn ogun ọdun ati jù bẹ̃ lọ.

25. Nitori Dafidi wipe, Oluwa Ọlọrun Israeli ti fi isimi fun awọn enia rẹ̀, on si ngbé Jerusalemu lailai:

26. Ati pẹlu awọn ọmọ Lefi: nwọn kì yio si tun rù ibugbe na mọ, ati gbogbo ohun elo rẹ̀ fun ìsin rẹ̀.

27. Nitori nipa ọ̀rọ ikẹhin Dafidi, ni kika iye awọn ọmọ Lefi lati ìwọn ogun ọdun ati jù bẹ̃ lọ:

28. Nitori iṣẹ wọn ni lati duro tì awọn ọmọ Aaroni, fun ìsin ile Oluwa, niti àgbala, ati niti iyẹwu, ati niti ṣiṣe ohun èlo wọnni ni mimọ́, ati iṣẹ ìsin ile Ọlọrun;

29. Ati fun àkara ifihàn, ati fun iyẹfun kikuna fun ẹbọ ọrẹ, ati fun àkara alaiwu, ati fun eyi ti a yan ninu awo pẹtẹ, ati fun eyi ti a dín, ati fun gbogbo oniruru òṣuwọn ati ìwọn;

30. Ati lati duro li orowurọ lati dupẹ ati lati yin Oluwa, ati bẹ̃ gẹgẹ li aṣalẹ;

31. Ati lati ru gbogbo ẹbọ ọrẹ sisun fun Oluwa li ọjọjọ isimi, ati li oṣù titun ati li ọjọ wọnni ti a pa li aṣẹ, ni iye, li ẹsẹsẹ gẹgẹ bi aṣẹ ti a pa fun wọn nigbagbogbo niwaju Oluwa:

32. Ati ki nwọn ki o ma tọju ẹṣọ agọ ajọ enia, ati ẹṣọ ibi mimọ́, ati ẹṣọ awọn ọmọ Aaroni arakunrin wọn, ni ìsin ile Oluwa.

1. Kro 23