1. Kro 23:14-17 Yorùbá Bibeli (YCE)

14. Ṣugbọn niti Mose enia Ọlọrun, a kà awọn ọmọ rẹ̀ pọ̀ mọ ẹ̀ya Lefi.

15. Awọn ọmọ Mose ni, Gerṣomu ati Elieseri.

16. Ninu awọn ọmọ Gerṣomu, Sebueli li olori.

17. Awọn ọmọ Elieseri ni Rehabiah olori. Elieseri kò si li ọmọ miran; ṣugbọn awọn ọmọ Rehabiah pọ̀ gidigidi.

1. Kro 23