1. NIGBATI Dafidi gbó, ti o si kún fun ọjọ, o fi Solomoni ọmọ rẹ̀ jẹ ọba lori Israeli.
2. O si kó gbogbo awọn ijoye Israeli jọ, ati awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi.
3. A si ka awọn ọmọ Lefi lati ẹni ọgbọ̀n ọdun ati jù bẹ̃ lọ: iye wọn nipa ori wọn, ọkunrin kọkan sí jẹ ẹgbã mọkandilogun.
4. Ninu wọnyi, ẹgbã mejila ni lati ma bojuto iṣẹ ile Oluwa; ẹgbãta si nṣe olori ati onidajọ:
5. Ẹgbaji si jẹ adena: ẹgbaji si fi ohun-elo ti mo ṣe lati buyìn, yìn Oluwa.
6. Dafidi si pín wọn ni ẹgbẹgbẹ lãrin awọn ọmọ Lefi, eyini ni Gerṣoni, Kohati, ati Merari.
7. Ninu awọn ọmọ Gerṣoni ni Laadani, ati Ṣimei.
8. Awọn ọmọ Laadani: Jehieli ni olori, ati Setamu, ati Joeli, mẹta.
9. Awọn ọmọ Ṣimei; Ṣelomiti, ati Hasieli, ati Harani, mẹta. Awọn wọnyi li olori awọn baba Laadani.