5. Joabu si fi apapọ iye awọn enia na fun Dafidi. Gbogbo Israeli jasi ẹgbẹrun ẹgbẹrun ati ọke marun enia ti nkọ idà: Juda si jasi ọkẹ mẹtalelogun le ẹgbãrun ọkunrin ti nkọ idà.
6. Ṣugbọn Lefi ati Benjamini ni kò kà pẹlu wọn: nitori ọ̀rọ ọba jẹ irira fun Joabu.
7. Nkan yi si buru loju Ọlọrun; o si kọlù Israeli.
8. Dafidi si wi fun Ọlọrun pe, Emi ti ṣẹ̀ gidigidi ni ṣiṣe nkan yi: ṣugbọn nisisiyi, emi bẹ̀ ọ, mu ẹ̀ṣẹ iranṣẹ rẹ kuro; nitoriti mo hùwa wère gidigidi.
9. Oluwa si wi fun Gadi, ariran Dafidi pe,
10. Lọ ki o si wi fun Dafidi pe, Bayi li Oluwa wi, mo fi nkan mẹta lọ̀ ọ: yàn ọkan ninu wọn ki emi ki o le ṣe e si ọ.
11. Bẹ̃ni Gadi tọ Dafidi wá, o si wi fun u pe, Bayi li Oluwa wi, yan fun ara rẹ,
12. Yala ọdun mẹta iyan, tabi iparun li oṣù mẹta niwaju awọn ọta rẹ, ti idà awọn ọta rẹ nle ọ ba; tabi idà Oluwa, ni ijọ mẹta, ani ajakalẹ àrun ni ilẹ na, ti angeli Oluwa o ma pani ja gbogbo àgbegbe Israeli. Njẹ nisisiyi rò o wò, esi wo ni emi o mu pada tọ̀ ẹniti o ran mi.