19. Dafidi si gòke lọ nipa ọ̀rọ Gadi, ti o sọ li orukọ Oluwa.
20. Ornani si yipada, o si ri angeli na; ati awọn ọmọ rẹ̀ mẹrin pẹlu rẹ̀ pa ara wọn mọ́. Njẹ Ornani npa ọka lọwọ.
21. Bi Dafidi si ti de ọdọ Ornani, Ornani si wò, o si ri Dafidi, o si ti ibi ilẹ ipaka rẹ̀ jade, o si wolẹ, o dojubolẹ fun Dafidi.
22. Dafidi si wi fun Ornani pe, Fun mi ni ibi ipaka yi, ki emi ki o le tẹ pẹpẹ kan nibẹ fun Oluwa; iwọ o si fi fun mi ni iye owo rẹ̀ pipe; ki a le da ajakalẹ arun duro lọdọ awọn enia.
23. Ornani si wi fun Dafidi pe, Mu u fun ra rẹ, si jẹ ki oluwa mi ọba ki o ṣe eyiti o dara loju rẹ̀: wò o mo fi awọn malu pẹlu fun ẹbọ-ọrẹ-sisun, ati ohun èlo ipaka fun igi, ati ọka fun ọrẹ onjẹ; mo fi gbogbo rẹ̀ fun ọ.
24. Dafidi ọba si wi fun Ornani pe, Bẹ̃kọ; ṣugbọn emi a rà a ni iye owo rẹ̀ pipe nitõtọ, nitoriti emi kì o mu eyi ti iṣe tirẹ fun Oluwa, bẹ̃ni emi kì o ru ẹbọ-ọrẹ sisun laiṣe inawo.
25. Bẹ̃ni Dafidi fi ẹgbẹta ṣekeli wura nipa iwọn fun Ornani fun ibẹ na.
26. Dafidi si tẹ pẹpẹ kan nibẹ fun Oluwa, o si ru ẹbọ ọrẹ-sisun ati ẹbọ ọpẹ, o si kepe Oluwa; on si fi iná da a li ohùn lati ọrun wá lori pẹpẹ ẹbọ-ọrẹ sisun na.