16. Nigbati awọn ara Siria ri pe a le wọn niwaju Israeli, nwọn ran onṣẹ, nwọn si fà awọn ara Siria ti mbẹ lòke odò: Ṣofaki olori ogun Hadareseri sì ṣiwaju wọn.
17. A si sọ fun Dafidi; on si ko gbogbo Israeli jọ, o si gòke odò Jordani o si yọ si wọn, o si tẹ ogun si wọn. Bẹ̃ni nigbati Dafidi tẹ ogun si awọn ara Siria, nwọn ba a jà.
18. Ṣugbọn awọn ara Siria sá niwaju Israeli, Dafidi si pa ẹ̃dẹgbarin enia ninu awọn ara Siria ti o wà ninu kẹkẹ́, ati ọkẹ-meji ẹlẹsẹ, o si pa Ṣofaki olori ogun na.
19. Nigbati awọn iranṣẹ Hadareseri ri pe a le wọn niwaju Israeli, nwọn ba Dafidi làja, nwọn si nsìn i: bẹ̃ni awọn ara Siria kò jẹ ràn awọn ọmọ Ammoni lọwọ mọ.