1. Kro 18:1-3 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. O SI ṣe lẹhin eyi, ni Dafidi kọlu awọn ara Filistia, o si ṣẹ́ wọn, o si gbà Gati ati ilu rẹ̀ lọwọ awọn ara Filistia.

2. O si kọlu Moabu, awọn ara Moabu si di iranṣẹ Dafidi, nwọn si mu ọrẹ wá.

3. Dafidi si kọlu Hadareseri ọba Soba ni Hamati bi o ti nlọ lati fi idi ijọba rẹ̀ mulẹ leti odò Euferate.

1. Kro 18