1. Kro 17:8-15 Yorùbá Bibeli (YCE)

8. Emi si ti wà pẹlu rẹ ni ibikibi ti iwọ ba lọ, emi si ti ké gbogbo awọn ọta rẹ kuro niwaju rẹ, emi o si ṣe ọ li olorukọ kan, bi orukọ awọn enia nla ti o ti wà li aiye.

9. Emi o si yan ibi kan fun Israeli awọn enia mi, emi o si gbìn wọn, ki nwọn le má gbe ipò wọn, a kì yio si ṣì wọn mọ; bẹ̃ni ọmọ buburu kì yio yọ wọn lẹnu mọ, bi ti atijọ;

10. Ati bi igba ti emi ti fi enia jẹ onidajọ lori awọn enia mi Israeli. Ati pẹlu emi o ṣẹgun gbogbo awọn ọta rẹ. Pẹlupẹlu mo ti sọ fun ọ pe, Oluwa yio kọle kan fun ọ.

11. Yio si ṣe, nigbati ọjọ rẹ ba pe, ti iwọ o lọ pẹlu awọn baba rẹ, ni emi o gbé iru-ọmọ rẹ dide lẹhin rẹ, ti yio jẹ ọkan ninu awọn ọmọ rẹ ọkunrin; emi o si fi idi ijọba rẹ̀ mulẹ.

12. On o kọ́ ile fun mi, emi o si fi idi itẹ rẹ̀ mulẹ lailai.

13. Emi o jẹ baba fun u, on o si jẹ ọmọ fun mi; emi kì yio si gbà ãnu mi kuro lọdọ rẹ̀, bi mo ti gbà a lọwọ ẹniti o ti wà ṣaju rẹ:

14. Ṣugbọn emi o fi idi rẹ̀ kalẹ ninu ile mi ati ninu ijọba mi lailai, a o si fi idi itẹ rẹ̀ mulẹ lailai.

15. Gẹgẹ bi gbogbo ọ̀rọ wọnyi, ati gẹgẹ bi gbogbo iran yi, bẹ̃ni Natani sọ fun Dafidi.

1. Kro 17