3. O si ṣe li oru kanna ni ọ̀rọ Ọlọrun tọ Natani wá, wipe,
4. Lọ, si sọ fun Dafidi iranṣẹ mi pe, Bayi li Oluwa wi, Iwọ kò gbọdọ kọ́ ile fun mi lati ma gbe.
5. Nitori emi kò ti igbe inu ile lati ọjọ ti mo ti mu Israeli gòke wá titi fi di oni yi; ṣugbọn emi nlọ lati agọ de agọ, ati lati ibugbe kan de keji.
6. Nibikibi ti mo ti nrin larin gbogbo Israeli, emi ha sọ̀rọ kan fun ọkan ninu awọn onidajọ Israeli, ti emi ti paṣẹ fun lati ma bọ awọn enia mi, emi ha ti wipe, Ẽṣe ti ẹnyin kò fi kọ́ ile igi kedari fun mi bi?