1. Kro 16:30-32 Yorùbá Bibeli (YCE)

30. Ẹ warìri niwaju rẹ̀, gbogbo aiye aiye pẹlu si fi idi mulẹ ti kì o fi le yi.

31. Jẹ ki awọn ọrun ki o yọ̀, si jẹ ki inu aiye ki o dùn; si jẹ ki a wi ninu awọn orilẹ-ède pe, Oluwa jọba.

32. Jẹ ki okun ki o ma ho, ati ẹkún rẹ̀: jẹ ki papa-oko tùtu ki o yọ̀, ati ohun gbogbo ti mbẹ ninu rẹ̀.

1. Kro 16