19. Nigbati ẹnyin wà ni kiun ni iye, ani diẹ kiun, ati atipo ninu rẹ̀.
20. Nwọn si nlọ lati orilẹ-ède de orilẹ-ède, ati lati ijọba kan de ọdọ enia miran;
21. On kò jẹ ki ẹnikẹni ki o ṣe wọn ni ìwọsi, nitõtọ, o ba awọn ọba wi nitori wọn,
22. Wipe, Ẹ má ṣe fi ọwọ kan ẹni-ororo mi, ẹ má si ṣe awọn woli mi ni ibi.
23. Ẹ kọrin titun si Oluwa gbogbo aiye; ẹ ma fi igbala rẹ̀ hàn lati ọjọ de ọjọ.
24. Ẹ sọ̀rọ ogo rẹ̀ ninu awọn keferi; ati iṣẹ-iyanu rẹ̀ ninu gbogbo enia.
25. Nitori titobi li Oluwa, o si ni iyìn gidigidi: on li o si ni ibẹ̀ru jù gbogbo oriṣa lọ.
26. Nitori pe gbogbo oriṣa awọn enia, ere ni nwọ́n: ṣugbọn Oluwa li o da awọn ọrun.