12. Ẹ ma ranti iṣẹ iyanu rẹ̀ ti o ti ṣe, iṣẹ àmi rẹ̀, ati idajọ ẹnu rẹ̀;
13. Ẹnyin iru-ọmọ Israeli iranṣẹ rẹ̀, ẹnyin ọmọ Jakobu ayanfẹ rẹ̀.
14. On ni Oluwa Ọlọrun wa, idajọ rẹ̀ mbẹ ni gbogbo aiye.
15. Ẹ ma ṣe iranti majẹmu rẹ̀ titi lai, ọ̀rọ ti o ti pa li aṣẹ fun ẹgbẹrun iran;
16. Majẹmu ti o ba Abrahamu da, ati ibura rẹ̀ fun Isaaki;
17. A si tẹnumọ eyi li ofin fun Jakobu, ati fun Israeli ni majẹmu aiyeraiye:
18. Wipe, Iwọ li emi o fi ilẹ Kenaani fun, ipin ilẹ-ini nyin.
19. Nigbati ẹnyin wà ni kiun ni iye, ani diẹ kiun, ati atipo ninu rẹ̀.