5. Awọn ara ilu Jebusi si wi fun Dafidi pe, Iwọ kò gbọdọ wọ̀ ihinyi wa. Ṣugbọn Dafidi kó ilu odi Sioni ti iṣe ilu Dafidi.
6. Dafidi si wipe, Ẹnikẹni ti o ba tetekọ kọlù awọn ara Jebusi ni yio ṣe olori ati balogun. Bẹ̃ni Joabu ọmọ Seruiah si tetekọ gòke lọ, o si jẹ olori.
7. Dafidi si ngbe inu ilu odi, nitorina ni nwọn fi npè e ni ilu Dafidi.
8. O si kọ́ ilu na yikakiri; ani lati Millo yikakiri: Joabu si tun iyokù ilu na ṣe.
9. Bẹ̃ni Dafidi nga, o si npọ̀ si i: nitori ti Oluwa awọn ọmọ-ogun wà pẹlu rẹ̀.
10. Wọnyi si ni olori awọn ọkunrin akọni ti Dafidi ni; awọn ti o fi ara wọn mọ ọ girigiri ni ijọba rẹ̀, pẹlu gbogbo Israeli, lati fi i jọba, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa fun Israeli.
11. Eyi ni iye awọn ọkunrin akọni ti Dafidi ni; Jaṣobeamu ọmọ Hakmoni, olori ninu awọn ọgbọ̀n balogun: on li o gbé ọ̀kọ rẹ̀ soke si ọ̃dunrun enia ti o pa lẹrikan.
12. Lẹhin rẹ̀ ni Eleaseri ọmọ Dodo, ara Ahohi, ẹniti iṣe ọkan ninu awọn akọni mẹta.
13. On wà pẹlu Dafidi ni Pasdammimu, nigbati awọn ara Filistia ko ara wọn jọ lati jagun, nibiti ilẹ-bĩri kan wà ti o kún fun ọkà barli; awọn enia si salọ kuro niwaju awọn ara Filistia.
14. Nwọn si duro jẹ li ãrin ilẹ-bĩri na, nwọn si gbà a, nwọn si pa awọn ara Filistia; Oluwa si fi igbala nla gbà wọn.
15. Awọn mẹta ninu awọn ọgbọ̀n balogun si sọ̀kalẹ tọ̀ Dafidi lọ sibi apata na, ninu iho Adullamu; ogun ara Filistia si do li afonifoji Refaimu.
16. Dafidi si mbẹ ninu ilu odi nigbana, ẹgbẹ-ogun awọn ara Filistia si mbẹ ni Betlehemu li akoko na.
17. Dafidi si pòngbẹ, o si wipe, Emi iba ri ẹni fun mi mu ninu omi kanga Betlehemu ti mbẹ leti ẹnu-bodè!