1. Kro 11:20-34 Yorùbá Bibeli (YCE)

20. Ati Abiṣai arakunrin Joabu, on li olori ninu awọn mẹta: nitoriti o gbé ọ̀kọ rẹ̀ soke si ọ̃dunrun o pa wọn, o si ni orukọ ninu awọn mẹta.

21. O ni ọla jù awọn mẹta ẹgbẹ ekeji lọ o si jẹ olori wọn: ṣugbọn kò to awọn mẹta iṣaju.

22. Benaiah, ọmọ Jehoiada, ọmọ akọni ọkunrin kan ti Kabseeli, ẹniti o pọ̀ ni iṣe agbara, o pa awọn ọmọ Arieli meji ti Moabu; on sọkalẹ, o si pa kiniun kan ninu iho lakoko sno.

23. O si pa ara Egipti kan, ọkunrin ti o si sigbọnlẹ igbọnwọ marun ni gigun rẹ̀; ati li ọwọ ara Egipti na ni ọ̀kọ kan wà bi idubu igi awunṣọ; o si sọ̀kalẹ tọ ọ lọ pẹlu ọpa, a si já ọ̀kọ li ọwọ ara Egipti na, o si fi ọ̀kọ rẹ̀ pa a.

24. Nkan wọnyi ni Benaiah ọmọ Jehoiada ṣe, o si li orukọ ninu awọn akọni mẹta.

25. Kiyesi i, o li ọla jù awọn ọ̀gbọn lọ, ṣugbọn kò to awọn mẹta iṣaju. Dafidi si fi ṣe olori awọn igbimọ ile rẹ̀.

26. Awọn akọni ọkunrin ọmọ ogun rẹ̀ ni Asaheli arakunrin Joabu, Elhanani, ọmọ Dodo, ara Betlehemu.

27. Sammotu, ara Harori, Helesi, ara Peloni,

28. Ira, ọmọ Ikkeṣi, ara Tekoa, Abieseri ara Anatoti,

29. Sibbekai, ara Husa, Ilai, ara Ahohi,

30. Maharai, ara Netofa, Heledi ọmọ Baana, ara Netofa.

31. Itai ọmọ Ribai ti Gibea, ti awọn ọmọ Benjamini, Benaiah ara Piratoni,

32. Hurai ti odò Gaaṣi, Abieli ara Arbati,

33. Asmafeti ara Baharumi, Eliaba ara Ṣaalboni.

34. Awọn ọmọ Haṣemu ara Gisoni, Jonatani ọmọ Sage, ara Harari.

1. Kro 11