1. AWỌN ara Filistia si ba Israeli jagun, awọn ọkunrin Israeli si sá niwaju awọn ara Filistia, nwọn fi ara pa, nwọn si ṣubu li òke Gilboa.
2. Awọn ara Filistia si lepa Saulu kikan, ati awọn ọmọ rẹ̀: awọn ara Filistia si pa Jonatani, ati Abinadabu, ati Melkiṣua, awọn ọmọ Saulu.
3. Ogun na si le fun Saulu, awọn tafàtafà si ba a, on si damu nitori awọn tafàtafà.
4. Nigbana ni Saulu wi fun ẹniti o ru ihamọra rẹ̀ pe, Fa idà rẹ yọ, ki o si fi gun mi, ki awọn alaikọla wọnyi ki o má ba wá fi mi ṣẹsin. Ṣugbọn ẹniti o ru ihamọra rẹ̀ kọ̀, nitori ẹ̀ru ba a gidigidi. Bẹ̃ni Saulu si mu idà, o si ṣubu le e.
5. Nigbati ẹniti o ru ihamọra rẹ̀ si ri pe Saulu kú, on na pẹlu si ṣubu le idà rẹ̀, o si kú.
6. Bẹ̃ni Saulu kú, ati awọn ọmọ rẹ̀ mẹtẹta, gbogbo ile rẹ̀ si kú ṣọkan.