1. Kor 8:6-9 Yorùbá Bibeli (YCE)

6. Ṣugbọn fun awa Ọlọrun kan ni mbẹ, Baba, lọwọ ẹniti ohun gbogbo ti wá, ati ti ẹniti gbogbo wa iṣe; ati Oluwa kanṣoṣo Jesu Kristi, nipasẹ ẹniti ohun gbogbo wà, ati awa nipasẹ rẹ̀.

7. Ṣugbọn ìmọ yi kò si ninu gbogbo enia: ṣugbọn awọn ẹlomiran ti o ti mbọriṣa pẹ titi fi di isisiyi jẹ ẹ bi ohun ti a fi rubọ si oriṣa; ati ẹri-ọkàn wọn ti o ṣe ailera si di alaimọ́.

8. Ṣugbọn onjẹ ki yio mu wa sunmọ Ọlọrun: nitoripe kì iṣe bi awa ba jẹ li awa san ju; tabi bi awa kò si jẹ li awa buru ju.

9. Ṣugbọn ẹ mã kiyesara ki omnira nyin yi ki o máṣe di ohun ikọsẹ fun awọn ti o ṣe ailera.

1. Kor 8