1. Kor 4:19-21 Yorùbá Bibeli (YCE)

19. Ṣugbọn emi ó tọ̀ nyin wá ni lọ̃lọ yi, bi Oluwa ba fẹ; kì si iṣe ọ̀rọ awọn ti ngberaga li emi o mọ̀, bikoṣe agbara.

20. Nitori ijọba Ọlọrun kì iṣe ninu ọ̀rọ, bikoṣe ninu agbara.

21. Kili ẹnyin nfẹ? emi ó ha tọ̀ nyin wá ti emi ti kùmọ bi, tabi ni ifẹ, ati ẹmí inututù?

1. Kor 4