1. Kor 16:5-16 Yorùbá Bibeli (YCE)

5. Ṣugbọn emi o tọ̀ nyin wá, nigbati emi ba ti kọja lọ larin Makedonia: nitori emi ó kọja larin Makedonia.

6. Boya emi ó si duro, ani, emi a si lo akoko otutu pẹlu nyin, ki ẹnyin ki o le sìn mi li ọ̀na àjo mi, nibikibi ti mo ba nlọ.

7. Nitori emi kò fẹ ri nyin li ọ̀na-ajò nisisiyi; nitori emi nreti ati duro lọdọ nyin nigba diẹ, bi Oluwa ba fẹ.

8. Ṣugbọn emi o duro ni Efesu titi di Pẹntikọsti.

9. Nitoripe ilẹkun nla ati aitase ṣi silẹ fun mi, ọ̀pọlọpọ si li awọn ọtá ti mbẹ.

10. Njẹ bi Timotiu ba de, ẹ jẹ́ ki o wà lọdọ nyin laibẹ̀ru: nitori on nṣe iṣẹ Oluwa, bi emi pẹlu ti nṣe.

11. Nitorina ki ẹnikẹni máṣe kẹgan rẹ̀. Ṣugbọn ẹ sìn i jade lọna-ajò li alafia, ki on ki o le tọ̀ mi wá: nitoriti emi nwò ọ̀na rẹ̀ pẹlu awọn arakunrin.

12. Ṣugbọn niti Apollo arakunrin wa, mo bẹ ẹ pupọ ki o tọ̀ nyin wá pẹlu awọn arakunrin: ṣugbọn kì iṣe ifẹ rẹ̀ rara lati wá nisisiyi; ṣugbọn on o wá nigbati o ba ni akokò ti o wọ̀.

13. Ẹ mã ṣọra, ẹ duro gangan ni igbagbọ́, ẹ ṣe bi ọkunrin, ẹ jẹ alagbara.

14. Ẹ mã fi ifẹ ṣe gbogbo nkan nyin.

15. Njẹ mo bẹ nyin, ará (ẹ sá mọ̀ ile Stefana, pe awọn ni akọso Akaia, ati pe, nwọn si ti fi ara wọn fun iṣẹ-iranṣẹ awọn enia mimọ́),

16. Ki ẹnyin ki o tẹriba fun irú awọn bawọnni, ati fun olukuluku olubaṣiṣẹ pọ̀ pẹlu wa ti o si nṣe lãla.

1. Kor 16